MyDugsiStart learning

Surah Al-Munafiqun in Yoruba: translation and audio

Surah 63 · المنافقون · The Hypocrites · 11 verses

Surah Al-Munafiqun verse by verse: the Arabic with a recitation you can repeat, the transliteration, and the Yoruba translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni. For the meaning of every word, see Surah Al-Munafiqun word by word in English.

Verse 1

إِذَا جَآءَكَ ٱلْمُنَـٰفِقُونَ قَالُوا۟ نَشْهَدُ إِنَّكَ لَرَسُولُ ٱللَّهِ ۗ وَٱللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّكَ لَرَسُولُهُۥ وَٱللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّ ٱلْمُنَـٰفِقِينَ لَكَـٰذِبُونَ

Transliteration idhā jāaka l-munāfiqūna qālū nashhadu innaka larasūlu l-lahi wal-lahu yaʿlamu innaka larasūluhu wal-lahu yashhadu inna l-munāfiqīna lakādhibūna

Yoruba Nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí bá wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n á wí pé: “À ń jẹ́rìí pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Allāhu ni ọ́.” Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ọ́. Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, òpùrọ́ ni wọ́n.

Verse 2

ٱتَّخَذُوٓا۟ أَيْمَـٰنَهُمْ جُنَّةً فَصَدُّوا۟ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ ۚ إِنَّهُمْ سَآءَ مَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ

Transliteration ittakhadhū aymānahum junnatan faṣaddū ʿan sabīli l-lahi innahum sāa mā kānū yaʿmalūna

Yoruba Wọ́n fi àwọn ìbúra wọn ṣe ààbò (fún ẹ̀mí ara wọn), wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.

Verse 3

ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ ءَامَنُوا۟ ثُمَّ كَفَرُوا۟ فَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ

Transliteration dhālika bi-annahum āmanū thumma kafarū faṭubiʿa ʿalā qulūbihim fahum lā yafqahūna

Yoruba (Wọ́n ṣe) ìyẹn nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, A ti fi èdídí dí ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́ àgbọ́yé.

Verse 4

۞ وَإِذَا رَأَيْتَهُمْ تُعْجِبُكَ أَجْسَامُهُمْ ۖ وَإِن يَقُولُوا۟ تَسْمَعْ لِقَوْلِهِمْ ۖ كَأَنَّهُمْ خُشُبٌ مُّسَنَّدَةٌ ۖ يَحْسَبُونَ كُلَّ صَيْحَةٍ عَلَيْهِمْ ۚ هُمُ ٱلْعَدُوُّ فَٱحْذَرْهُمْ ۚ قَـٰتَلَهُمُ ٱللَّهُ ۖ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ

Transliteration wa-idhā ra-aytahum tuʿ'jibuka ajsāmuhum wa-in yaqūlū tasmaʿ liqawlihim ka-annahum khushubun musannadatun yaḥsabūna kulla ṣayḥatin ʿalayhim humu l-ʿaduwu fa-iḥ'dharhum qātalahumu l-lahu annā yu'fakūna

Yoruba Nígbà tí o bá rí wọn, ìrísí wọn yóò jọ ọ́ lójú. Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ìwọ yóò tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sì dà bí igi tí wọ́n gbé ti ògiri.Wọ́n sì ń lérò pé gbogbo igbe (ìbòsí) ń bẹ lórí wọn (nípa ìṣọ̀bẹ-ṣèlu wọn).2 Ọ̀tá ni wọ́n. Nítorí náà, ṣọ́ra fún wọn. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!

Verse 5

وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا۟ يَسْتَغْفِرْ لَكُمْ رَسُولُ ٱللَّهِ لَوَّوْا۟ رُءُوسَهُمْ وَرَأَيْتَهُمْ يَصُدُّونَ وَهُم مُّسْتَكْبِرُونَ

Transliteration wa-idhā qīla lahum taʿālaw yastaghfir lakum rasūlu l-lahi lawwaw ruūsahum wara-aytahum yaṣuddūna wahum mus'takbirūna

Yoruba Àti pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá kí Òjíṣẹ́ ba yín tọrọ àforíjìn.” Wọ́n á gbúnrí. O sì máa rí wọn tí wọn yóò máa gbúnrí lọ, tí wọn yóò máa ṣègbéraga.

Verse 6

سَوَآءٌ عَلَيْهِمْ أَسْتَغْفَرْتَ لَهُمْ أَمْ لَمْ تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ لَن يَغْفِرَ ٱللَّهُ لَهُمْ ۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهْدِى ٱلْقَوْمَ ٱلْفَـٰسِقِينَ

Transliteration sawāon ʿalayhim astaghfarta lahum am lam tastaghfir lahum lan yaghfira l-lahu lahum inna l-laha lā yahdī l-qawma l-fāsiqīna

Yoruba Bákan náà ni fún wọn; yálà o bá wọn tọrọ àforíjìn tàbí o ò bá wọn tọrọ àforíjìn.Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu kò nií fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

Verse 7

هُمُ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ لَا تُنفِقُوا۟ عَلَىٰ مَنْ عِندَ رَسُولِ ٱللَّهِ حَتَّىٰ يَنفَضُّوا۟ ۗ وَلِلَّهِ خَزَآئِنُ ٱلسَّمَـٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ وَلَـٰكِنَّ ٱلْمُنَـٰفِقِينَ لَا يَفْقَهُونَ

Transliteration humu alladhīna yaqūlūna lā tunfiqū ʿalā man ʿinda rasūli l-lahi ḥattā yanfaḍḍū walillahi khazāinu l-samāwāti wal-arḍi walākinna l-munāfiqīna lā yafqahūna

Yoruba Àwọn ni àwọn tó ń wí pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ná owó fún àwọn tó wà lọ́dọ̀ Ójíṣẹ́ Allāhu títí wọn yóò fi fọ́nká. Ti Allāhu sì ni àwọn ilé ọrọ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò gbọ́ àgbọ́yé.

Verse 8

يَقُولُونَ لَئِن رَّجَعْنَآ إِلَى ٱلْمَدِينَةِ لَيُخْرِجَنَّ ٱلْأَعَزُّ مِنْهَا ٱلْأَذَلَّ ۚ وَلِلَّهِ ٱلْعِزَّةُ وَلِرَسُولِهِۦ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَلَـٰكِنَّ ٱلْمُنَـٰفِقِينَ لَا يَعْلَمُونَ

Transliteration yaqūlūna la-in rajaʿnā ilā l-madīnati layukh'rijanna l-aʿazu min'hā l-adhala walillahi l-ʿizatu walirasūlihi walil'mu'minīna walākinna l-munāfiqīna lā yaʿlamūna

Yoruba Wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú tí a bá padà dé sínú ìlú Mọdīnah, ńṣe ni àwọn alágbára (ìlú) yóò yọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ jáde kúrò nínú ìlú.” Agbára sì ń jẹ́ ti Allāhu, àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò mọ̀.

Verse 9

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ لَا تُلْهِكُمْ أَمْوَٰلُكُمْ وَلَآ أَوْلَـٰدُكُمْ عَن ذِكْرِ ٱللَّهِ ۚ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَأُو۟لَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلْخَـٰسِرُونَ

Transliteration yāayyuhā alladhīna āmanū lā tul'hikum amwālukum walā awlādukum ʿan dhik'ri l-lahi waman yafʿal dhālika fa-ulāika humu l-khāsirūna

Yoruba Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín kó àìrójú ba yín níbi ìrántí Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kó sínú (àìrójú) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.

Verse 10

وَأَنفِقُوا۟ مِن مَّا رَزَقْنَـٰكُم مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِىَ أَحَدَكُمُ ٱلْمَوْتُ فَيَقُولَ رَبِّ لَوْلَآ أَخَّرْتَنِىٓ إِلَىٰٓ أَجَلٍ قَرِيبٍ فَأَصَّدَّقَ وَأَكُن مِّنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Transliteration wa-anfiqū min mā razaqnākum min qabli an yatiya aḥadakumu l-mawtu fayaqūla rabbi lawlā akhartanī ilā ajalin qarībin fa-aṣṣaddaqa wa-akun mina l-ṣāliḥīna

Yoruba Ẹ ná nínú ohun tí A pèsè fún yín ṣíwájú kí ikú tó dé bá ẹnì kan yín, kí ó wá wí pé: “Olúwa mi, kí ó sì jẹ́ pé O lọ́ mi lára sí i títí di ìgbà kan tó súnmọ́, èmi ìbá sì lè máa tọrẹ, èmi ìbá sì wà lára àwọn ẹni rere.”

Verse 11

وَلَن يُؤَخِّرَ ٱللَّهُ نَفْسًا إِذَا جَآءَ أَجَلُهَا ۚ وَٱللَّهُ خَبِيرٌۢ بِمَا تَعْمَلُونَ

Transliteration walan yu-akhira l-lahu nafsan idhā jāa ajaluhā wal-lahu khabīrun bimā taʿmalūna

Yoruba Allāhu kò sì níí lọ́ ẹ̀mí kan lára nígbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ bá dé. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Read Surah Al-Munafiqun in another language

All languages

All 114 surahs in Yoruba: the Qur’an in Yoruba.

Learn it in MyDugsi

Yoruba translation: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni, from Quran.com. Transliteration: Quran.com. Recitation: Mishary Alafasy, from EveryAyah.com. MyDugsi is a learning aid, not a replacement for a qualified teacher.